Ohun ti Amosun lese tolemu Inumi dun......Segun Sowunmi



........Asiko ti to fun egbe
oselu APC lati fijoba
sile.

Ogbeni Segun
Sowunmi to n foju
sona lati dije dupo
omo ile igbimo asofin
agba niluu Abuja
(House of
Representative) ti so
pe nkan kan soso to
le mu koun dariji
Gomina ipinle Ogun,
Ibikunle Amosun pelu
awon ise akanse to
loun n se nipinle
Ogun, to je pe ilu
Abeokuta to ti wa
nikan lo n se e si ni
pe to ba le je ki oko
baluu (Aeroplane)
bale sipinle naa.
Segun Sowunmi so
pe bo tile je pe oun
ko ba Gomina
Amosun ja, nitori pe
arakunrin oun ni,
tawon si jo ni itan
papo, sugbon oun ko
le la oju oun sile lati
ma so awon ibi to ku
si gege bawon se je
omo ilu kan naa.
O soro yi lakoko to n
gbawon oniroyin ero
ayelujara, iyen
National Association
of Nigerian Bloggers
(NANB) lalejo lai pe yi
niluu Abeokuta, nibi
to ti so pe ijoba
adanikan se ni
Amosun n se nipinle
Ogun, ti ko si fawon
komisana atawon
amugbalegbe e lenu
oro.
Sowunmi so pe ko ye
ki gomina to loun
feran awon araalu e
maa se awon akanse
ise silu to ti wa nikan,
bi ko se pe ko je ki
gbogbo awon ipinle e
jegbadun e, ki won si
je mudun-mudun
ijoba awa-ara-wa.
O so siwaju pe bi won
ba wo awon ise ti
Gomina Amosun loun
n se nipinle e, won
yoo rii pe ilu
Abeokuta to je olu ilu
ipinle Ogun tokunrin
naa ti wa lo n sise ju
si, ti ko si ronu
idagbasoke sawon ilu
to ku, o ni ko bojumu
to.
Ninu oro e, o so pe
“Nipa idagbasoke
igbalode ati tit un
awon ona se lona
igbalode niluu
Abeokuta ti mo ti wa,
maa dupe lowo
Gomina Amosun,
sugbon lesekese ni
maa beere lowo e pe
se o ti de awon
agbegbe to ku nipinle
Ogun bii; Ado-Odo
Ota, Igbesa, Agbara/
Lusada, Mowe/Ibafo,
Alagbole/Ifo, Akute/
Ajuwon, sugbon to ba
so pe rara, maa gba a
niyanju wi pe ko lo
sibe lati lo wo nkan to
n sele.
“To ba so pe oun ti de
be, ma a beere lowo
e pe se lero okan e, bi
won se n sejoba lo se
n se yen, to ba so pe
beeni, maa ni ko ye
ko ri bee, bi won se n
sejoba ko niyen.
“Ma a beere lowo e
pe yatro si afara oloke
(bridge) atawon
opopona to ja geere,
ki lo tun ro pe ipinle
Ogun nilo gege bi
idagbasoke, to ba so
pe ko sii, ma a so fun
un pe kii se be. Ma a
beere lowo e pe se
awon ile ti ko wulo to
pe nileewe igbalode
(Model School) to ko
kaakiri, ti ko wulo lo
fe e so pe o je
idagbasoke leka eto
eko, to ba so pe
beeni, maa so fun un
pe ko ye ko ri bee,
nise lo ye ko se awon
atunto liana eko, ko si
tun awon ileewe to ti
fe e wo tan ko. Eto
ilera naa pelu awon
nkan ti mo maa
menuba wi pe ko loo
satunse le lori.
“Ko seni to le soro
ninu isejoba Amosun,
o maa soro ki e to le
gboro lenu enikeni
ninu awon komisana
e yato si bi won ba fe
e paro. Ko ye ko ri be
e. Ma a dupe lowo e
nitori pe ko je awon
osise ijoba lowo osu,
ti ko sit un si wahala
laarin oun atawon
Oba nipinle Ogun.
“Mo fe ki e mo daju
wi pe ijoba e ti fe e
tan, awon omo ipinle
Ogun si ti fun un ni
anfaani lati sin won
lemeeji. Nkan kan
soso to n kan mi
lominu ni eni ti yoo
gbajoba lowo
Amosun, nitori pe se
ni aya mi n ja ki eni
naa ma tele liana ti
Amosun fi sile. Bi
omo Yewa ba wole
gege bi won se n fe,
ko ma lo je pe ile
Yewa loun naa maa
doju ko lati fi gbesan.
Bee lominu n kan mi
lori gbese ti eni ti yoo
gbajoba lowo e maa
ba nile. Nitori wi pe
awon eeyan ko soro,
ko tunmo si wi pe
won ko ri, ko tunmo
si wi pe won ko mo
nkan to n lo.
“Mo lo si Badagry
lodun to koja, mo si
gba ona Agbara lo,
nigba ti mo de
agbegbe yen, ti mo ri
awon ileese nla-nla
nibe pelu awon ona
to gba ibe koja, aanu
se mi, latari iya ti won
n je lori aini ona to ja
geere ti mo le rin lai
fese ko. Wi pe ona
kan je ijoba apapo ko
tunmo si wi pe ijoba
ipinle ko le sise de be
lati je kawon eeyan
jegbadun mudun-
mudun ijoba awa-ara-
wa.
“Nkan kan soso le mu
ki n dariji Gomina
Amosun ni to ba le je
ki oko baluu wo ipinle
Ogun gege bo se so
pe oun maa se koun
to o lo. Ti eyi ba ti
see se, ko soro mo.
Eeyan mi ni, kii se ota
mi, ati jo ni itan papo
ri nigba kan. Nkan ti
mo n gbadura si
Olorun nip e ko fun
wa lawon adari to
nironu to dara lati
gbajoba bi awon adari
bii Oloye Olusegun
Osoba, Gbenga Daniel
ati Amosun funra e.”
Nigba to n soro lori
isejoba egbe oselu
All Progressive
Congress (APC)
lorileede Naijiria,
paapaa ijoba Aare
Muhammadu Buhari,
Segun Sowunmi so
pe asiko ti to fawon
omo orileede yi lati
loo gba kaadi idibo
alalope (Permanent
Voter Card), PVC won
ki asiko idibo to o de,
nitori pe asiko lati
gbajoba lowo won ti
to.
O sapejuwe ijoba APC
gege bi ijoba to ti
kuna latari awon ileri
manigbagbe ti won
se lasiko ipolongo
idibo odun 2015, wi
pe awon yoo so owo
dola kan di naira kan,
tawon yoo si maa
fawon odo ti won ko
nise lowo legberun
marun-marun
losoosu, ti won ko sir
ii se, paapaa bi won
tun se seleri wi pe
awon yoo ja owo epo
bentiroolu wale lati
naira metadinlogorun
(97) naira si ogoji
naira, to je pe pabo lo
ja si.
Bakan naa lo bu enu
ate lu Asiwaju Bola
Ahmed Tinubu latari
bo se lewaju awon
omo ile Oduduwa lo
sabe awon Fulani to n
pawon omo orileede
yi nipakupa ti Aare
Buhari ko si so
nkankan lori e.
O ni bi inu Tinubu ba
dun sib awon Fulani
se n pawon omo leyin
Kristi atawon ti kii se
eya ti Buhari ti jade
wa, dajudaju, okunrin
naa ti kuna lati dale
awon omo Oloogbe
Obafemi Awolowo.
Bee lo gbosuba fun
Oloye Olusegun
Obasanjo fun leta to
ko lati fi tako ijoba
Aare Buhari latari bo
se n sejoba aibikita
emi ati dukia, paapaa
alaafia awon omo
orileede yi. O ni bi
Obasanjo ba le ni
igboya lati ko iru leta
naa, ko si nkan to di
awon bii Abdulsalam,
Sagari, Sonekan,
Babangida, paapaa
Tinubu lowo lati dide
soro, tabi ko iru leta
be e.
O ni kii se pe bi won
ba ko leta naa, Aare
Buhari yoo fipo sile
wi pe oun ko se e mo,
sugbon lati mo awon
ibi to ku si, ko si tun
ero ara e pa lori bo se
n sejoba, atawon to
yan sijoba e.
NIgba to n soro lori
ipinu e lati dije dupo
asojusofin lati ekun
Abeokuta South, o so
pe idagbasoke ilu oun
lo je oun logun, toun
si rii pe awon ti won ti
n ran lo siluu Abuja
lati soju won, kii se
nkan to ye ki won se.
O ni orisirisi ona
igbalode loun ni lati
mu idagbasoke wo
ipinle Ogun, paapaa
nijoba ibile apapo
toun ti fe e jade, lara
e ni ri ro awon odo
lagbara lati da duro,
lai duro de enikeni lati
jeun.
Sowunmi so pe kii se
pe ri ra okada lo le
mu idagbasoke wo
ilu, nitori bi
asojusofin ba so pe
oun n ra okada tabi
keke maruwa fawon
eeyan, a a je pe se
niru eni bee fe e so
gbogbo eeyan di
olokada laarin ilu
niyen.
Bee lo rawo ebe
sawon araalu lati ran
oun lo soju won niluu
Abuja tasiko ba to,
nitori pe oun ri ara
oun gege bi eni to
kun oju osuwon lati
soju won nilu Abuja.

No comments